Àìsáyà 31:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í kéàní kìnnìún ńlá lórí ẹranànjẹ rẹ̀bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàntí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojúu rẹ̀,ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọnakitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wáláti jagun lórí òkè Ṣíhónì àti lórí ibi gíga rẹ̀.

5. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò Jérúsálẹ́mù,Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”

6. Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì.

7. Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ẹ yín ti ṣe.

Àìsáyà 31