Àìsáyà 30:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ẹgbẹ̀rún yóò sánípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan;nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn úngbogbo yín lẹ ó ṣálọ,tí a ó fi yín sílẹ̀àti gẹ́gẹ́ bí igi àṣíá ní orí òkè,gẹ́gẹ́ bí àṣíá lórí òkè.”

18. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́;ó dìde láti ṣàánú fún ọ.Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!

19. Ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì, tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìwọ kì yóò ṣunkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.

20. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò farasin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.

21. Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsi, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.”

22. Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”

Àìsáyà 30