Àìsáyà 28:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Kíyèsíì, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le tí ó sì lágbára,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wọ́ yìnyín àti bí àtẹ̀gùn apanirun,gẹ́gẹ́ bí àrọ̀ọ̀dá òjò àti òjò tí ómú ẹ̀kún omi wá,òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.

3. Òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣe ìgbéraga àwọnọ̀mùtí Éfáímù,òun ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀.

4. Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkóórèbí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ọ rẹ̀,òun a sì mì ín.

5. Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò jẹ́ adé tí ó lógo,Òdòdó tí ó lẹ́wàfún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.

6. Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́-òdodofún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́-ìdájọ́àti oríṣun agbárafún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padàní ẹnubodè.

Àìsáyà 28