Àìsáyà 16:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí náà mo ṣunkún, gẹ́gẹ́ bí Jáṣérì ṣe ṣunkún,fún àwọn àjàrà Ṣíbínà.Ìwọ Hẹ́ṣíbónì, Ìwọ Élíálẹ̀,mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!Igbe ayọ̀ lórí àwọn èṣo pípọ́n rẹàti lórí ìkóórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.

10. Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrònínú ọgbà-igi eléso rẹ;kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbíkígbe nínu ọgbà-àjàrà:ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.

11. Ọkàn mi kérora fún Móábù gẹ́gẹ́ bí i hápù,àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Háréṣétì.

12. Nígbà tí Móábù farahàn ní ibi gíga rẹ̀,ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúràòfo ni ó já sí.

Àìsáyà 16