Àìsáyà 14:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Báwo ni ìwọ ṣe ṣubúlulẹ̀ láti ọ̀run wá,ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayéÌwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀ èdè ba rí!

13. Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókèga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpèjọní ṣónṣó orí òkè mímọ́.

14. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọ̀sánmọ̀;Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ògo.”

15. Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọlọ sí ìṣàlẹ̀ ọ̀gbun.

16. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtìtí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.

17. Ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó dojú àwọn ìlú ńlá ńlá bolẹ̀tí kò sì jẹ́ kí àwọn ìgbèkùn padà sílé?”

Àìsáyà 14