32. Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nóbùwọn yóò kan sáárá,ní òkè ọmọbìnrin Ṣíhónìní òkè Jérúsálẹ́mù.
33. Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára.Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀Àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.
34. Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké,Lẹ́bánónì yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.