2 Sámúẹ́lì 8:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ó sì fi àwọn ológun sí Édómù; àti ní gbogbo Édómù yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Édómù sì wá sin Dáfídì, Olúwa sì fún Dáfídì ní ìṣẹgún níbikíbi tí ó ń lọ.

15. Dáfídì sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì; Dáfídì sì ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀.

16. Jóábù ọmọ Sérúyà ni ó sì ń ṣe olórí ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì ń ṣe akọ̀wé.

17. Sádókù ọmọ Áhítúbì, àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì, ni àwọn àlùfáà; Sérúyà a sì máa ṣe akọ̀wé.

2 Sámúẹ́lì 8