29. Ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń sọ ọ̀ràn ara rẹ fún mi èmi sáà ti wí pé, kí ìwọ àti Ṣíbà pín ilẹ̀ náà.”
30. Méfíbóṣétì sì wí fún ọba pé, “Jẹ́ kí ó mú gbogbo rẹ̀, kí Olúwa mi ọba sáà ti padà bọ̀ wá ilé rẹ̀ ni àlàáfíà.”
31. Básíláì ará Gílíádì sì sọ̀kalẹ̀ láti Rogelímù wá, ó sì bá ọba gòkè odò Jódánì, láti ṣe ìkẹ́ rẹ̀ sí ìkọjá odò Jódánì.
32. Básíláì sì jẹ́ arúgbó ọkùnrìn gidigidi, ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sì ni: ó sì pèsè ohun jíjẹ fún ọba nígbà tí ó ti wà ní Máhánáímù; nítorí pé ọkùnrin ọlọ́lá ni òun ń ṣe.
33. Ọba sì wí fún Básíláì pé, “Ìwọ wá bá mi gòkè odò, èmi ó sì máa pésè fún ọ ní Jérúsálẹ́mù.”
34. Básíláì sì wí fún ọba pé, “Ọjọ́ mélòó ni ọdún ẹ̀mí mi kù, tí èmi ó fi bá ọba gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù
35. Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sáà ni èmi lónìí: ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ló mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí? Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọ́rin bí, ǹjẹ́ nítorí kínni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún Olúwa mi ọba.
36. Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jódánì; èésì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi.
37. Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhámù ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá Olúwa mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.”
38. Ọba sì dáhùn wí pé, “Kímhámù yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un; ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣeé fún ọ.”