14. Ábúsálómù àti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wí pé, “Ìmọ̀ Húṣáì ará Áríkì sàn ju ìmọ̀ Áhítófélì lọ! Nítorí Olúwa fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Áhítófélì po.” Nítorí kí Olúwa lè mú ibi wá sórí Ábúsálómù.
15. Húṣáì sì wí fún Sádókù àti fún Ábíátarì àwọn àlùfáà pé, “Bàyìí ni Áhítófélì ti bá Ábúsálómù àti àwọn àgbà Ísírẹ́lì dámọ̀ràn: báyìí lèmi sì báa dámọ̀ràn.
16. Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dáfídì pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má báa gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ”
17. Jónátanì àti Áhímásì sì dúró ní Énrógélì ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dáfídì ọba nítorí pé kí a má báà rí wọn pé wọ́n wọ ìlú.