16. Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Èlíjà sọ.
17. Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú.
18. Obìnrin náà sì wí fún Èlíjà pé, “Kí lo ní sí mi, ènìyàn Ọlọ́run? Ìwọ ha tọ̀ mí wá láti mú ẹ̀ṣẹ̀ mi wá sí ìrántí, àti láti pa mí ní ọmọ?”
19. Èlíjà sì wí fún un pé, “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀.
20. Nígbà náà ni ó sì képe Olúwa wí pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ ha mú ibi wá bá opó náà pẹ̀lú lọ́dọ̀ ẹni tí èmi ń ṣe àtìpó, nípa pípa ọmọ rẹ̀?”
21. Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, ó sì képe Olúwa pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá!”
22. Olúwa sì gbọ́ igbe Èlíjà, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí.