Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, iwọ kò dàbí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi.