5. Ṣùgbọ́n Olúwa ti sọ fún Áhíjà pé, “Kíyèsí i, aya Jéróbóámù ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”
6. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Áhíjà sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jéróbóámù. Kíló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ.
7. Lọ, sọ fún Jéróbóámù pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórì lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.