1 Ọba 1:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ṣé nǹkan yìí ni Olúwa mi ọba ti ṣe láìjẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ?”

28. Nígbà náà ni Dáfídì ọba wí pé, “Pe Bátíṣébà wọlé wá.” Ó sì wá ṣíwájú ọba, ó sì dúró níwájú rẹ̀.

29. Ọba sì búrá pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti wà ẹni tí ó ti gbàmí kúrò nínú gbogbo wàhálà,

30. Lónìí dandan ni èmi yóò gbé ohun tí mo ti fi Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún yọ pé: Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, àti pé yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi ní ipò mi.”

1 Ọba 1