1 Kọ́ríńtì 14:33-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà.Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ijọ ènìyàn mímọ́

34. Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ijọ: nítorí a kò fí fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ ki wọn wà lábẹ́ itẹríbá, bí ó ṣe rí ni gbogbo àpéjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

35. Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn bèèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.

36. Kí ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tabi ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá?

1 Kọ́ríńtì 14