1 Kọ́ríńtì 13:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbógbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

8. Ìfẹ̀ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bún ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.

9. Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọ tẹ̀lẹ́ ní apá kan.

10. Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apákan yóò dópin.

1 Kọ́ríńtì 13