Tit 2:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN iwọ mã sọ ohun ti o yẹ si ẹkọ́ ti o yè kõro:

2. Ki awọn àgba ọkunrin jẹ ẹni iwọntunwọnsin, ẹni-ọ̀wọ, alairekọja, ẹniti o yè kõro ni igbagbọ́, ni ifẹ, ni sũru.

Tit 2