Sek 9:2-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ati Hamati pẹlu yio ṣe ãla rẹ̀: Tire ati Sidoni bi o tilẹ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi.

3. Tire si mọ odi lile fun ara rẹ̀, o si ko fàdakà jọ bi ekuru, ati wurà daradara bi ẹrẹ̀ ita.

4. Kiye si i, Oluwa yio tá a nù, yio si kọlu ipá rẹ̀ ninu okun; a o si fi iná jẹ ẹ run.

5. Aṣkeloni yio ri i, yio si bẹ̀ru; Gasa pẹlu yio ri i, yio si kãnu gidigidi, ati Ekroni: nitori oju o tì ireti rẹ̀: ọba yio si ṣegbe kuro ni Gasa, a kì o si gbe Aṣkeloni.

6. Ọmọ alè yio si gbe inu Aṣdodi, emi o si ke irira awọn Filistini kuro.

7. Emi o si mu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro li ẹnu rẹ̀, ati ohun irira rẹ̀ wọnni kuro lãrin ehín rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o kù, ani on na yio jẹ ti Ọlọrun wa, yio si jẹ bi bãlẹ kan ni Juda, ati Ekroni bi Jebusi.

8. Emi o si dó yi ilẹ mi ka nitori ogun, nitori ẹniti nkọja lọ, ati nitori ẹniti npada bọ̀: kò si aninilara ti yio là wọn já mọ: nitori nisisiyi ni mo fi oju mi ri.

9. Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ.

10. Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye.

11. Ni tirẹ pẹlu, emi o fi ẹjẹ majẹmu rẹ rán awọn igbèkun rẹ jade kuro ninu ihò ti kò li omi.

12. Ẹ pada si odi agbara, ẹnyin onde ireti: ani loni yi emi sọ pe, emi o san a fun ọ ni igbàmejì.

13. Nitori mo fa Juda le bi ọrun mi, mo si fi Efraimu kún u, mo si gbe awọn ọmọ rẹ ọkunrin dide, iwọ Sioni, si awọn ọmọ rẹ ọkunrin, iwọ ilẹ Griki, mo ṣe ọ bi idà alagbara.

Sek 9