22. Nitõtọ ọ̀pọlọpọ enia, ati awọn alagbara orilẹ-ède yio wá lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Jerusalemu; ati lati gbadura niwaju Oluwa.
23. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, li ọjọ wọnni yio ṣẹ, ni ọkunrin mẹwa lati inu gbogbo ède ati orilẹ-ède yio dì i mú, ani yio dì eti aṣọ ẹniti iṣe Ju mu, wipe, A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ́ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ.