8. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Sekariah wá, wipe,
9. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Dá idajọ otitọ, ki ẹ si ṣe ãnu ati iyọ́nu olukuluku si arakunrin rẹ̀.
10. Má si ṣe ni opó lara, tabi alainibaba, alejo, tabi talakà; ki ẹnikẹni ninu nyin ki o máṣe gbèro ibi li ọkàn si arakunrin rẹ̀.
11. Ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gbọ́, nwọn si gùn ejika, nwọn si di eti wọn, ki nwọn ki o má bà gbọ́.
12. Ani nwọn ṣe aiya wọn bi okuta adamanti, ki nwọn ki o má ba gbọ́ ofin, ati ọ̀rọ ti Ọluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ rán nipa ọwọ awọn woli iṣãju wá: ibinu nla si de lati ọdọ Ọluwa awọn ọmọ-ogun wá.
13. O si ṣe, gẹgẹ bi o ti kigbe, ti nwọn kò si fẹ igbọ́, bẹ̃ni nwọn kigbe, ti emi kò si fẹ igbọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.