Sek 7:6-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nigbati ẹ si jẹ, ati nigbati ẹ mu, fun ara nyin ki ẹnyin ha jẹ, ati fun ara nyin ki ẹnyin ha mu?

7. Wọnyi kì ọ̀rọ ti Oluwa ti kigbe lati ọdọ awọn woli iṣãju wá, nigbati a ngbe Jerusalemu, ti o si wà li alafia, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ti o yi i ka kiri, nigbati a ngbe gusù ati pẹtẹlẹ?

8. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Sekariah wá, wipe,

9. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Dá idajọ otitọ, ki ẹ si ṣe ãnu ati iyọ́nu olukuluku si arakunrin rẹ̀.

10. Má si ṣe ni opó lara, tabi alainibaba, alejo, tabi talakà; ki ẹnikẹni ninu nyin ki o máṣe gbèro ibi li ọkàn si arakunrin rẹ̀.

11. Ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gbọ́, nwọn si gùn ejika, nwọn si di eti wọn, ki nwọn ki o má bà gbọ́.

Sek 7