Sọ fun gbogbo awọn enia ilẹ na, ati fun awọn alufa, wipe, Nigbati ẹnyin gbawẹ̀ ti ẹ si ṣọ̀fọ li oṣù karun ati keje, ani fun ãdọrin ọdun wọnni, ẹnyin ha gbawẹ̀ si mi rara, ani si emi?