Sek 6:4-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti mba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi, oluwa mi?

5. Angeli na si dahùn o si wi fun mi pe, Wọnyi ni awọn ẹmi mẹrin ti ọrun, ti njade lọ kuro ni iduro niwaju Oluwa gbogbo aiye.

6. Awọn ẹṣin dudu ti o wà ninu rẹ̀ jade lọ si ilẹ ariwa; awọn funfun si jade tẹ̀le wọn; awọn adíkalà si jade lọ si ihà ilẹ gusù.

Sek 6