1. KIYESI i, ọjọ Oluwa mbọ̀, a o si pin ikogun rẹ lãrin rẹ.
2. Nitori emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si Jerusalemu fun ogun; a o si kó ilu na, a o si kó awọn ile, a o si bà awọn obinrin jẹ, abọ̀ ilu na yio lọ si igbèkun, a kì yio si ké iyokù awọn enia na kuro ni ilu na.
3. Nigbana ni Oluwa yio jade lọ, yio si ba awọn orilẹ-ède wọnni jà, gẹgẹ bi iti ijà li ọjọ ogun.