Sek 12:2-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Kiye si i, emi o sọ Jerusalemu di ago iwarìri si gbogbo enia yika, nigbati nwọn o do tì Juda ati Jerusalemu.

3. Li ọjọ na li emi o sọ Jerusalemu di ẹrù okuta fun gbogbo enia: gbogbo awọn ti o ba si fi dẹrù pa ara wọn li a o ke si wẹwẹ, bi gbogbo awọn orilẹ-ède aiye tilẹ ko ara wọn jọ si i.

4. Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o fi itagìri lù gbogbo ẹṣin, ati fi wère lu ẹniti ngùn u; emi o si ṣi oju mi si ile Juda, emi o si bu ifọju lù gbogbo ẹṣin ti enia na.

5. Ati awọn bãlẹ Juda yio si wi li ọkàn wọn pe, Awọn ara Jerusalemu li agbara mi nipa Oluwa Ọlọrun wọn.

6. Li ọjọ na li emi o ṣe awọn bãlẹ Juda bi ãrò iná kan lãrin igi, ati bi ètùfù iná lãrin ití; nwọn o si jẹ gbogbo awọn enia run yika lapa ọ̀tun ati lapa osi: a o si tun ma gbe Jerusalemu ni ipo rẹ̀, ani Jerusalemu.

Sek 12