Sek 12:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa fun Israeli, li Oluwa wi, ẹni ti o nnà awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ aiye sọlẹ, ti o si mọ ẹmi enia ti mbẹ ni inu rẹ̀.

2. Kiye si i, emi o sọ Jerusalemu di ago iwarìri si gbogbo enia yika, nigbati nwọn o do tì Juda ati Jerusalemu.

3. Li ọjọ na li emi o sọ Jerusalemu di ẹrù okuta fun gbogbo enia: gbogbo awọn ti o ba si fi dẹrù pa ara wọn li a o ke si wẹwẹ, bi gbogbo awọn orilẹ-ède aiye tilẹ ko ara wọn jọ si i.

4. Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o fi itagìri lù gbogbo ẹṣin, ati fi wère lu ẹniti ngùn u; emi o si ṣi oju mi si ile Juda, emi o si bu ifọju lù gbogbo ẹṣin ti enia na.

5. Ati awọn bãlẹ Juda yio si wi li ọkàn wọn pe, Awọn ara Jerusalemu li agbara mi nipa Oluwa Ọlọrun wọn.

6. Li ọjọ na li emi o ṣe awọn bãlẹ Juda bi ãrò iná kan lãrin igi, ati bi ètùfù iná lãrin ití; nwọn o si jẹ gbogbo awọn enia run yika lapa ọ̀tun ati lapa osi: a o si tun ma gbe Jerusalemu ni ipo rẹ̀, ani Jerusalemu.

7. Oluwa pẹlu yio kọ́ tète gba agọ Juda là na, ki ogo ile Dafidi ati ogo awọn ara Jerusalemu ma bà gbe ara wọn ga si Juda.

Sek 12