Sek 11:6-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nitori emi kì yio ṣãnu fun awọn ara ilẹ na mọ, li Oluwa wi; si kiye si i, emi o fi olukuluku enia le aladugbo rẹ̀ lọwọ, ati le ọwọ ọba rẹ̀: nwọn o si fọ́ ilẹ na, emi kì yio si gbà wọn lọwọ wọn.

7. Emi o si bọ́ ẹran abọ́pa, ani ẹnyin otoṣi ninu ọwọ́ ẹran. Mo si mu ọpa meji sọdọ; mo pe ọkan ni Ẹwà, mo si pe ekeji ni Amure; mo si bọ́ ọwọ́-ẹran na.

8. Oluṣọ agutan mẹta ni mo si ke kuro li oṣu kan; ọkàn mi si korira wọn, ọkàn wọn pẹlu si korira mi.

9. Mo si wipe, emi kì yio bọ nyin: eyi ti nkú lọ, jẹ ki o kú; eyi ti a o ba si ke kuro, jẹ ki a ke e kuro; ki olukuluku ninu awọn iyokù jẹ ẹran-ara ẹnikeji rẹ̀.

10. Mo si mu ọpa mi, ani Ẹwà, mo si ṣẹ ẹ si meji, ki emi ba le dà majẹmu mi ti mo ti ba gbogbo awọn enia ni da.

11. O si dá li ọjọ na; bẹ̃ni awọn otoṣi ninu ọwọ́-ẹran nì ti o duro tì mi mọ̀ pe, ọ̀rọ Oluwa ni.

12. Mo si wi fun wọn pe, Bi o ba dara li oju nyin, ẹ fun mi ni owo-ọ̀ya mi: bi bẹ̃kọ, ẹ jọwọ rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn wọ̀n ọgbọ̀n owo fadakà fun iye mi.

13. Oluwa si wi fun mi pe, Sọ ọ si amọkòko: iye daradara na ti nwọn yọwó mi si. Mo si mu ọgbọ̀n owo fadakà na, mo si sọ wọn si amọkòko ni ile Oluwa.

Sek 11