Sef 3:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EGBE ni fun ọlọ̀tẹ ati alaimọ́, fun ilu aninilara nì.

2. On kò fetisi ohùn na; on kò gba ẹkọ́; on kò gbẹkẹ̀le Oluwa; on kò sunmọ ọdọ Ọlọrun rẹ̀.

3. Awọn olori rẹ̀ ti o wà lãrin rẹ̀ kiniun ti nke ramùramù ni nwọn; awọn onidajọ rẹ̀ ikõkò aṣãlẹ ni nwọn; nwọn kò sán egungun titi di owurọ̀.

4. Awọn woli rẹ̀ gberaga, nwọn si jẹ ẹlẹtàn enia: awọn alufa rẹ̀ ti ba ibi mimọ́ jẹ: nwọn ti rú ofin.

Sef 3