8. Emi ti gbọ́ ẹgàn Moabu, ati ẹlẹyà awọn ọmọ Ammoni, nipa eyiti nwọn ti kẹgàn awọn enia mi, ti nwọn si ti gbe ara wọn ga si agbègbe wọn.
9. Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ọlọrun Israeli, Dajudaju Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni bi Gomorra, bi titàn wèrepe, ati bi ihò iyọ, ati ìdahoro titi lai, iyokù awọn enia mi o kó wọn, iyokù awọn orilẹ-ède mi yio si jogun wọn.
10. Eyi ni nwọn o ni nitori igberaga wọn, nitoripe nwọn ti kẹgàn, nwọn si ti gbe ara wọn ga si enia Oluwa awọn ọmọ-ogun.
11. Oluwa yio jẹ ibẹ̀ru fun wọn: nitori on o mu ki gbogbo òriṣa ilẹ aiye ki o rù; enia yio si ma sìn i, olukuluku lati ipò rẹ̀ wá, ani gbogbo erekùṣu awọn keferi.
12. Ẹnyin ara Etiopia pẹlu, a o fi idà mi pa nyin.
13. On o si nà ọwọ́ rẹ̀ si ihà ariwa, yio si pa Assiria run; yio si sọ Ninefe di ahoro, ati di gbigbẹ bi aginjù.
14. Agbo-ẹran yio si dùbulẹ li ãrin rẹ̀, gbogbo ẹranko awọn orilẹ-ède: ati ẹiyẹ òfu ati õrẹ̀ yio ma gbe atẹrigbà rẹ̀, ohùn wọn yio kọrin li oju fèrese; idahoro yio wà ninu iloro: nitoriti on o ṣi iṣẹ kedari silẹ.
15. Eyi ni ilu alayọ̀ na ti o ti joko lainani ti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ni, kò si si ẹnikan ti mbẹ lẹhìn mi: on ha ti ṣe di ahoro bayi, ibùgbe fun ẹranko lati dubulẹ si! olukuluku ẹniti o ba kọja lọdọ rẹ̀ yio pòṣe yio si mì ọwọ́ rẹ̀.