1. Ẹ kó ara nyin jọ pọ̀, ani, ẹ kójọ pọ̀ orilẹ-ède ti kò nani;
2. Ki a to pa aṣẹ na, ki ọjọ na to kọja bi iyàngbò, ki gbigboná ibinu Oluwa to de ba nyin, ki ọjọ ibinu Oluwa ki o to de ba nyin.
3. Ẹ wá Oluwa, gbogbo ẹnyin ọlọkàn tutù aiye, ti nṣe idajọ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwa-pẹ̀lẹ: boya a o pa nyin mọ li ọjọ ibinu Oluwa.
4. Nitoripe a o kọ̀ Gasa silẹ, Aṣkeloni yio si dahoro: nwọn o le Aṣdodu jade li ọsangangan, a o si fà Ekronu tu kuro.
5. Egbe ni fun awọn ẹniti ngbe agbègbe okun, orilẹ-ède awọn ara Kereti! ọ̀rọ Oluwa dojukọ nyin; iwọ Kenaani, ilẹ awọn ara Filistia, emi o tilẹ pa ọ run, ti ẹnikan kì yio gbe ibẹ̀ mọ.
6. Agbègbe okun yio si jẹ ibujoko ati agọ fun awọn olùṣọ agùtan, ati agbo fun agbo-ẹran.
7. Agbègbe na yio si wà fun iyokù ile Juda; nwọn o jẹ̀ li ori wọn: ni ile Aṣkeloni wọnni ni nwọn o dùbulẹ li aṣãlẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wọn yio bẹ̀ wọn wò, yio si yi igbèkun wọn padà kuro.