7. Pa ẹnu rẹ mọ niwaju Oluwa Ọlọrun: nitoriti ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ: nitori Oluwa ti pesè ẹbọ kan silẹ̀, o si ti yà awọn alapèjẹ rẹ̀ si mimọ́.
8. Yio si ṣe li ọjọ ẹbọ Oluwa, ti emi o bẹ̀ awọn olori wò, ati awọn ọmọ ọba, ati gbogbo iru awọn ti o wọ̀ ajèji aṣọ.
9. Li ọjọ na gan li emi o bẹ̀ gbogbo awọn ti nfò le iloro wò pẹlu, ti nfi ìwà-ipá on ẹ̀tan kún ile oluwa wọn.
10. Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ohùn ẹkún yio ti ihà bodè-ẹja wá, ati hihu lati ihà keji wá, ati iro nla lati oke-kékèké wọnni wá.
11. Hu, ẹnyin ara Maktẹsi, nitoripe gbogbo enia oniṣòwo li a ti ke lu ilẹ; gbogbo awọn ẹniti o nrù fàdakà li a ke kuro.
12. Yio si ṣe li akokò na, li emi o fi fitilà wá Jerusalemu kiri, emi o si bẹ̀ awọn enia ti o silẹ sinu gẹ̀dẹgẹdẹ̀ wọn wò: awọn ti nwi li ọkàn wọn pe, Oluwa kì yio ṣe rere, bẹ̃ni kì yio ṣe buburu.