11. Hu, ẹnyin ara Maktẹsi, nitoripe gbogbo enia oniṣòwo li a ti ke lu ilẹ; gbogbo awọn ẹniti o nrù fàdakà li a ke kuro.
12. Yio si ṣe li akokò na, li emi o fi fitilà wá Jerusalemu kiri, emi o si bẹ̀ awọn enia ti o silẹ sinu gẹ̀dẹgẹdẹ̀ wọn wò: awọn ti nwi li ọkàn wọn pe, Oluwa kì yio ṣe rere, bẹ̃ni kì yio ṣe buburu.
13. Nitorina ogun wọn o di ikógun, ati ilẹ wọn yio di ahoro: nwọn o kọ́ ile pẹlu, ṣugbọn nwọn kì yio gbe inu wọn, nwọn o si gbìn ọgbà àjara, ṣugbọn nwọn kì yio mu ọti-waini inu rẹ̀.
14. Ọjọ nla Oluwa kù si dẹ̀dẹ, o kù si dẹ̀dẹ̀, o si nyara kánkan, ani ohùn ọjọ Oluwa: alagbara ọkunrin yio sọkun kikorò nibẹ̀.
15. Ọjọ na ọjọ ibinu ni, ọjọ iyọnu, ati ipọnju, ọjọ ofò ati idahoro, ọjọ okùnkun ọti okùdu, ọjọ kũku ati okunkun biribiri,
16. Ọjọ ipè ati idagirì si ilu olodi wọnni ati si iṣọ giga wọnni.
17. Emi o si mu ipọnju wá bá enia, ti nwọn o ma rìn bi afọju, nitori nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa: ẹjẹ̀ wọn li a o si tú jade bi ekuru, ati ẹran-ara wọn bi igbẹ.
18. Fàdakà wọn tabi wurà wọn kì yio lè gbà wọn li ọjọ ìbinu Oluwa: ṣugbọn gbogbo ilẹ̀ na li a o fi iná ijowu rẹ̀ parun: nitori on o fi iyara mu gbogbo awọn ti ngbe ilẹ na kuro.