Sef 1:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Sefaniah wá ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hisikiah, li ọjọ Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda.

2. Oluwa wipe, emi o mu gbogbo nkan kuro lori ilẹ na patapata.

3. Emi o mu enia ati ẹranko kuro; emi o mu ẹiyẹ oju ọrun kuro, ati ẹja inu okun, ati ohun idigbòlu pẹlu awọn enia buburu; emi o si ké enia kuro lori ilẹ, ni Oluwa wi.

4. Emi o nà ọwọ́ mi pẹlu sori Juda, ati sori gbogbo ara Jerusalemu; emi o si ké iyokù Baali kuro nihinyi, ati orukọ Kemarimu pẹlu awọn alufa;

5. Ati awọn ti nsìn ogun ọrun lori orule: awọn ti nsìn, ti nfi Oluwa bura, ti si nfi Malkomu bura;

6. Ati awọn ẹniti o yipadà kuro lọdọ Oluwa; ati awọn ẹniti kò ti wá Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò si bère rẹ̀.

7. Pa ẹnu rẹ mọ niwaju Oluwa Ọlọrun: nitoriti ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ: nitori Oluwa ti pesè ẹbọ kan silẹ̀, o si ti yà awọn alapèjẹ rẹ̀ si mimọ́.

8. Yio si ṣe li ọjọ ẹbọ Oluwa, ti emi o bẹ̀ awọn olori wò, ati awọn ọmọ ọba, ati gbogbo iru awọn ti o wọ̀ ajèji aṣọ.

9. Li ọjọ na gan li emi o bẹ̀ gbogbo awọn ti nfò le iloro wò pẹlu, ti nfi ìwà-ipá on ẹ̀tan kún ile oluwa wọn.

10. Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ohùn ẹkún yio ti ihà bodè-ẹja wá, ati hihu lati ihà keji wá, ati iro nla lati oke-kékèké wọnni wá.

11. Hu, ẹnyin ara Maktẹsi, nitoripe gbogbo enia oniṣòwo li a ti ke lu ilẹ; gbogbo awọn ẹniti o nrù fàdakà li a ke kuro.

Sef 1