Rut 2:9-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Jẹ ki oju rẹ ki o wà ninu oko ti nwọn nkore rẹ̀, ki iwọ ki o si ma tẹle wọn: emi kò ha ti kìlọ fun awọn ọmọkunrin ki nwọn ki o máṣe tọ́ ọ? ati nigbati ongbẹ ba ngbẹ ọ, lọ si ibi àmu, ki o si mu ninu eyiti awọn ọmọkunrin ti pọn.

10. Nigbana ni o wolẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba silẹ, o si wi fun u pe, Eṣe ti mo ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹ̃ni alejo li emi?

11. Boasi si da a lohùn o si wi fun u pe, Gbogbo ohun ti iwọ ṣe fun iya-ọkọ rẹ lati ìgba ikú ọkọ rẹ, li a ti rò fun mi patapata: ati bi iwọ ti fi baba ati iya rẹ, ati ilẹ ibi rẹ silẹ, ti o si wá sọdọ awọn enia ti iwọ kò mọ̀ rí.

12. Ki OLUWA ki o san ẹsan iṣẹ rẹ, ẹsan kikún ni ki a san fun ọ lati ọwọ́ OLUWA Ọlọrun Israeli wá, labẹ apa-iyẹ́ ẹniti iwọ wá gbẹkẹle.

13. Nigbana li o wipe, OLUWA mi, jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ; iwọ sá tù mi ninu, iwọ sá si ti sọ̀rọ rere fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, bi o tilẹ ṣe pe emi kò ri bi ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ rẹ obinrin.

14. Li akokò onjẹ, Boasi si wi fun u pe, Iwọ sunmọ ihin, ki o si jẹ ninu onjẹ, ki o si fi òkele rẹ bọ̀ inu ọti kíkan. On si joko lẹba ọdọ awọn olukore: o si nawọ́ ọkà didin si i, o si jẹ, o si yó, o si kùsilẹ.

15. Nigbati o si dide lati peṣẹ́-ọkà, Boasi si paṣẹ fun awọn ọmọkunrin rẹ̀, wipe, Ẹ jẹ ki o peṣẹ́-ọkà ani ninu awọn ití, ẹ má si ṣe bá a wi.

16. Ki ẹ si yọ diẹ ninu ití fun u, ki ẹ si fi i silẹ, ki ẹ si jẹ ki o ṣà a, ẹ má si ṣe bá a wi.

17. Bẹ̃li o peṣẹ́-ọkà li oko titi o fi di aṣalẹ, o si gún eyiti o kójọ, o si to bi òṣuwọn efa ọkà-barle kan.

18. O si gbé e, o si lọ si ilu: iya-ọkọ rẹ̀ si ri ẽṣẹ́ ti o pa: on si mú jade ninu eyiti o kù lẹhin ti o yó, o si fi fun u.

19. Iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ gbé peṣẹ́ li oni? nibo ni iwọ si ṣiṣẹ? ibukún ni fun ẹniti o fiyesi ọ. O si sọ ọdọ ẹniti on ṣiṣẹ fun iya-ọkọ rẹ̀, o si wipe, Boasi li orukọ ọkunrin ti mo ṣiṣẹ lọdọ rẹ̀ li oni.

20. Naomi si wi fun aya-ọmọ rẹ̀ pe, Ibukún ni fun u lati ọdọ OLUWA wá, ẹniti kò dẹkun ore rẹ̀ lati ṣe fun awọn alãye, ati fun awọn okú. Naomi si wi fun u pe, ọkunrin na sunmọ wa, ibatan ti o sunmọ wa ni.

Rut 2