Rut 2:3-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. On si lọ, o si dé oko, o si peṣẹ́-ọkà lẹhin awọn olukore: o si wa jẹ pe apa oko ti o bọ si jẹ́ ti Boasi, ti iṣe ibatan Elimeleki.

4. Si kiyesi i, Boasi ti Betilehemu wá, o si wi fun awọn olukore pe, Ki OLUWA ki o wà pẹlu nyin. Nwọn si da a lohùn pe, Ki OLUWA ki o bukún fun ọ.

5. Nigbana ni Boasi wi fun iranṣẹ rẹ̀ ti a fi ṣe olori awọn olukore pe, Ọmọbinrin tani yi?

6. Iranṣẹ na ti a fi ṣe olori awọn olukore dahùn, o si wipe, Ọmọbinrin ara Moabu ni, ti o bá Naomi ti ilẹ Moabu wa.

7. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ma peṣẹ-ọkà, ki emi si ma ṣà lẹhin awọn olukore ninu ití: bẹ̃li o wá, o si duro ani lati owurọ̀ titi di isisiyi, bikoṣe ìgba diẹ ti o simi ninu ile.

Rut 2