Rom 9:27-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Isaiah si kigbe nitori Israeli pe, Bi iye awọn ọmọ Israeli bá ri bi iyanrin okun, apakan li a ó gbala.

28. Nitori Oluwa yio mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ lori ilẹ aiye, yio pari rẹ̀, yio si ke e kúru li ododo.

29. Ati bi Isaiah ti wi tẹlẹ, Bikoṣe bi Oluwa awọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, a ba si ti sọ wa dabi Gomora.

30. Njẹ kili awa o ha wi? Pe awọn Keferi, ti kò lepa ododo, ọwọ́ wọn tẹ̀ ododo, ṣugbọn ododo ti o ti inu igbala wá ni.

31. Ṣugbọn Israeli ti nlepa ofin ododo, ọwọ́ wọn kò tẹ̀ ofin ododo.

32. Nitori kini? nitori nwọn ko wá a nipa igbagbọ́, ṣugbọn bi ẹnipe nipa iṣẹ ofin. Nitori nwọn kọsẹ lara okuta ikọsẹ ni;

33. Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kiyesi i, mo gbé okuta ikọsẹ ati àpata idugbolu kalẹ ni Sioni: ẹnikẹni ti o ba si gbà a gbọ, oju kì yio ti i.

Rom 9