27. Isaiah si kigbe nitori Israeli pe, Bi iye awọn ọmọ Israeli bá ri bi iyanrin okun, apakan li a ó gbala.
28. Nitori Oluwa yio mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ lori ilẹ aiye, yio pari rẹ̀, yio si ke e kúru li ododo.
29. Ati bi Isaiah ti wi tẹlẹ, Bikoṣe bi Oluwa awọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, a ba si ti sọ wa dabi Gomora.
30. Njẹ kili awa o ha wi? Pe awọn Keferi, ti kò lepa ododo, ọwọ́ wọn tẹ̀ ododo, ṣugbọn ododo ti o ti inu igbala wá ni.
31. Ṣugbọn Israeli ti nlepa ofin ododo, ọwọ́ wọn kò tẹ̀ ofin ododo.
32. Nitori kini? nitori nwọn ko wá a nipa igbagbọ́, ṣugbọn bi ẹnipe nipa iṣẹ ofin. Nitori nwọn kọsẹ lara okuta ikọsẹ ni;