Rom 9:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OTITỌ li emi nsọ ninu Kristi, emi kò ṣeke, ọkàn mi si njẹ mi li ẹrí ninu Ẹmí Mimọ́,

2. Pe mo ni ibinujẹ pupọ, ati ikãnu igbagbogbo li ọkàn mi.

3. Nitori mo fẹrẹ le gbadura pe ki a ké emi tikarami kuro lọdọ Kristi, nitori awọn ará mi, awọn ibatan mi nipa ti ara:

4. Awọn ẹniti iṣe Israeli; ti awọn ẹniti isọdọmọ iṣe, ati ogo, ati majẹmu, ati ifunnilofin, ati ìsin Ọlọrun, ati awọn ileri;

5. Ti ẹniti awọn baba iṣe, ati lati ọdọ awọn ẹniti Kristi ti wá nipa ti ara, ẹniti o bori ohun gbogbo, Ọlọrun olubukún lailai. Amin.

Rom 9