Rom 7:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Njẹ nisisiyi kì iṣe emi li o nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti o ngbe inu mi.

18. Nitori emi mọ̀ pe ko si ohun rere kan ti ngbe inu mi, eyini ninu ara mi: nitori ifẹ ohun ti o dara mbẹ fun mi, ṣugbọn ọna ati ṣe e li emi kò ri.

19. Nitori ire ti emi fẹ emi kò ṣe: ṣugbọn buburu ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe.

20. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe, emi ki nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti ngbe inu mi.

21. Njẹ mo ri niti ofin pe, bi emi ti nfẹ lati mã ṣe rere, buburu a ma wà lọdọ mi.

22. Inu mi sá dùn si ofin Ọlọrun nipa ẹni ti inu:

23. Ṣugbọn mo ri ofin miran ninu awọn ẹ̀ya ara mi, ti mba ofin inu mi jagun ti o si ndì mi ni igbekun wá fun ofin ẹ̀ṣẹ, ti o mbẹ ninu awọn ẹ̀ya ara mi.

Rom 7