1. TABI ẹnyin ha ṣe alaimọ̀, ará (nitori awọn ti o mọ̀ ofin li emi mba sọrọ), pe ofin ni ipa lori enia niwọn igbati o ba wà lãye?
2. Nitori obinrin ti o ni ọkọ, ìwọn igbati ọkọ na wà lãye, a fi ofin dè e mọ́ ọkọ na; ṣugbọn bi ọkọ na ba kú, a tú u silẹ kuro ninu ofin ọkọ na.
3. Njẹ bi o ba ni ọkọ miran nigbati ọkọ rẹ̀ wà lãye, panṣaga li a o pè e: ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o bọ lọwọ ofin na; ki yio si jẹ panṣaga bi o ba ni ọkọ miran.
4. Bẹ̃li ẹnyin ará mi, ẹnyin pẹlu ti di okú si ofin nipa ara Kristi: ki ẹnyin kì o le ni ẹlomiran, ani ẹniti a jinde kuro ninu okú, ki awa ki o le so eso fun Ọlọrun.
5. Nitori igbati awa wà nipa ti ara, ifẹkufẹ ẹ̀ṣẹ, ti o wà nipa ofin, o nṣiṣẹ ninu awọn ẹ̀ya ara wa lati so eso si ikú.