1. NJẸ awa o ha ti wi? Ki awa ki o ha joko ninu ẹ̀ṣẹ, ki ore-ọfẹ ki o le ma pọ̀ si i?
2. Ki a má ri. Awa ẹniti o ti kú si ẹ̀ṣẹ, awa o ha ṣe wà lãye ninu rẹ̀ mọ́?
3. Tabi ẹ kò mọ̀ pe, gbogbo wa ti a ti baptisi sinu Kristi Jesu, a ti baptisi wa sinu ikú rẹ̀?
4. Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa.
5. Nitori bi a ba ti so wa pọ̀ pẹlu rẹ̀ nipa afarawe ikú rẹ̀, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rẹ̀:
6. Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́.
7. Nitori ẹniti o kú, o bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ.