Ṣugbọn kì iṣe bi ẹ̀ṣẹ bẹ̃ si li ẹ̀bun ọfẹ. Nitori bi nipa ẹ̀ṣẹ ẹnikan, ẹni pupọ kú, melomelo li ore-ọfẹ Ọlọrun, ati ẹ̀bun ninu ore-ọfẹ ọkunrin kan, Jesu Kristi, di pupọ fun ẹni pupọ.