Rom 16:21-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Timotiu, alabaṣiṣẹ mi, ati Lukiu, ati Jasoni, ati Sosipateru, awọn ibatan mi, ki nyin.

22. Emi Tertiu ti nkọ Episteli yi, kí nyin ninu Oluwa.

23. Gaiu, bãle mi, ati ti gbogbo ijọ, ki nyin. Erastu, olutọju iṣura ilu, kí nyin, ati Kuartu arakunrin.

24. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

25. Njẹ fun ẹniti o li agbara lati fi ẹsẹ nyin mulẹ gẹgẹ bi ihinrere mi ati iwasu Jesu Kristi, gẹgẹ bi iṣipaya ohun ijinlẹ, ti a ti pamọ́ lati igba aiyeraiye,

26. Ti a si nfihàn nisisiyi, ati nipa iwe-mimọ́ awọn woli, gẹgẹ bi ofin Ọlọrun aiyeraiye, ti a nfihàn fun gbogbo orilẹ-ède si igbọràn igbagbọ́:

27. Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo nipasẹ Jesu Kristi li ogo wà fun lailai. Amin.

Rom 16