Rom 14:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN ẹniti o ba ṣe ailera ni igbagbọ́ ẹ gbà a, li aitọpinpin iṣiyemeji rẹ̀.

2. Ẹnikan gbagbọ́ pe on le mã jẹ ohun gbogbo: ẹlomiran ti o si ṣe alailera njẹ ewebẹ.

3. Ki ẹniti njẹ máṣe kẹgan ẹniti kò jẹ; ki ẹniti kò si jẹ ki o máṣe dá ẹniti njẹ lẹjọ: nitori Ọlọrun ti gbà a.

4. Tani iwọ ti ndá ọmọ-ọdọ ẹlomĩ lẹjọ? loju oluwa rẹ̀ li o duro, tabi ti o ṣubu. Nitotọ a o si mu u duro: nitori Oluwa ni agbara lati mu u duro.

5. Ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ kan jù omiran lọ: ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ gbogbo bakanna. Ki olukuluku ki o da ara rẹ̀ loju ni inu ara rẹ̀.

6. Ẹniti o ba nkiyesi ọjọ, o nkiyesi i fun Oluwa; ẹniti kò ba si kiyesi ọjọ, fun Oluwa ni kò kiyesi i. Ẹniti njẹun, o njẹun fun Oluwa, nitori o ndupẹ lọwọ Ọlọrun; ẹniti kò ba si jẹun, fun Oluwa ni kò jẹun, o si ndupẹ lọwọ Ọlọrun.

Rom 14