10. Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju.
11. Niti iṣẹ ṣiṣe, ẹ má ṣe ọlẹ; ẹ mã ni igbona ọkàn; ẹ mã sìn Oluwa;
12. Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura;
13. Ẹ mã pese fun aini awọn enia mimọ́; ẹ fi ara nyin fun alejò iṣe.
14. Ẹ mã súre fun awọn ti nṣe inunibini si nyin: ẹ mã sure, ẹ má si ṣepè.
15. Awọn ti nyọ̀, ẹ mã ba wọn yọ̀, awọn ti nsọkun, ẹ mã ba wọn sọkun.
16. Ẹ mã wà ni inu kanna si ara nyin. Ẹ máṣe tọju ohun gíga, ṣugbọn ẹ mã tẹle awọn onirẹlẹ. Ẹ máṣe jẹ ọlọ́gbọn li oju ara nyin.