10. Ki oju wọn ki o ṣokun, ki nwọn ki o má le riran, ki o si tẹ̀ ẹhin wọn ba nigbagbogbo.
11. Njẹ mo ni, Nwọn ha kọsẹ̀ ki nwọn ki o le ṣubu? Ki a má ri: ṣugbọn nipa iṣubu wọn, igbala dé ọdọ awọn Keferi, lati mu wọn jowú.
12. Ṣugbọn bi iṣubu wọn ba di ọrọ̀ aiye, ati bi ifasẹhin wọn ba di ọrọ̀ awọn Keferi; melomelo ni kíkún wọn?
13. Ẹnyin ti iṣe Keferi li emi sa mba sọrọ, niwọnbi emi ti jẹ aposteli awọn Keferi, mo gbé oyè mi ga:
14. Bi o le ṣe ki emi ki o le mu awọn ará mi jowú, ati ki emi ki o le gbà diẹ là ninu wọn.