Owe 8:9-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Gbangba ni gbogbo wọn jasi fun ẹniti o yé, o si tọ́ fun awọn ti o nwá ìmọ ri.

10. Gbà ẹkọ mi, kì si iṣe fadaka; si gbà ìmọ jù wura àṣayan lọ.

11. Nitori ti ìmọ jù iyùn lọ; ohun gbogbo ti a le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e.

12. Emi ọgbọ́n li o mba imoye gbe, emi ìmọ si ri imoye ironu.

13. Ibẹ̀ru Oluwa ni ikorira ibi: irera, ati igberaga, ati ọ̀na ibi, ati ẹnu arekereke, ni mo korira.

14. Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara.

15. Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ.

Owe 8