26. Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye.
27. Nigbati o nṣe ipilẹ awọn ọrun, emi wà nibẹ: nigbati o fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun.
28. Nigbati o sọ awọsanma lọjọ̀ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibu:
29. Nigbati o fi aṣẹ rẹ̀ fun okun, ki omi rẹ̀ ki o máṣe kọja ẹnu rẹ̀: ati ofin rẹ̀ fun ipilẹ aiye.
30. Nigbana, emi wà lọdọ rẹ̀, bi oniṣẹ: emi si jẹ didùn-inu rẹ̀ lojojumọ, emi nyọ̀ nigbagbogbo niwaju rẹ̀;
31. Emi nyọ̀ ni ibi-itẹdo aiye rẹ̀: didùn-inu mi si wà sipa awọn ọmọ enia.
32. Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukún ni fun awọn ti o tẹle ọ̀na mi:
33. Gbọ́ ẹkọ́, ki ẹnyin ki o si gbọ́n, má si ṣe jẹ ki o lọ.