Owe 8:14-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara.

15. Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ.

16. Nipasẹ mi li awọn ijoye nṣolori, ati awọn ọ̀lọtọ̀, ani gbogbo awọn onidajọ aiye.

Owe 8