6. Li oju ferese ile mi li emi sa bojuwò lãrin ferese mi.
7. Mo si ri ninu awọn òpe, mo kiyesi ninu awọn ọmọkunrin, ọmọkunrin kan ti oye kù fun,
8. O nkọja lọ ni igboro li eti igun ile rẹ̀; o si lọ si ọ̀na ile rẹ̀,
9. Ni wiriwiri imọlẹ, li aṣãlẹ, li oru dudu ati òkunkun:
10. Si kiyesi i, obinrin kan pade rẹ̀, o wọ aṣọ panṣaga, alarekereke aiya.
11. (O jẹ alariwo ati alagidi; ẹsẹ rẹ̀ kì iduro ni ile rẹ̀.
12. Nisisiyi o jade, nisisiyi o wà ni igboro, o si mba ni ibi igun ile gbogbo.)
13. Bẹ̃li o dì i mu, o si fẹnu kò o li ẹnu, o si fi ọ̀yájú wi fun u pe,
14. Ọrẹ́, alafia mbẹ lọwọ mi, loni ni mo ti san ẹjẹ́ mi.
15. Nitorina ni mo ṣe jade wá pade rẹ, lati ṣe afẹri oju rẹ, emi si ri ọ.