26. Nitoripe nipasẹ agbere obinrin li enia fi idi oniṣù-akara kan: ṣugbọn aya enia a ma wá iye rẹ̀ daradara.
27. Ọkunrin le gbé iná lé aiya rẹ̀ ki aṣọ rẹ̀ ki o má jona?
28. Ẹnikan ha le gun ori ẹyin-iná gbigbona, ki ẹsẹ rẹ̀ ki o má jona?
29. Bẹ̃li ẹniti o wọle tọ obinrin ẹnikeji rẹ̀ lọ; ẹnikẹni ti o fi ọwọ bà a, kì yio wà li ailẹṣẹ̀.
30. Nwọn ki igàn ole, bi o ba ṣe pe, o jale lati tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrùn, nigbati ebi npa a;
31. Ṣugbọn bi a ba mu u, yio san a pada niwọ̀n meje; gbogbo ini ile rẹ̀ ni yio fi san ẹsan.
32. Ṣugbọn ẹni ti o ba ba obinrin ṣe panṣaga, oye kù fun u: ẹniti o ba ṣe e yio pa ẹmi ara rẹ run.
33. Ọgbẹ ati àbuku ni yio ni; ẹ̀gan rẹ̀ kì yio si parẹ́ kuro.
34. Nitori owú ni ibinu ọkunrin: nitorina kì yio dasi li ọjọ ẹsan.
35. On kì yio nani owo idande, bẹ̃ni inu rẹ̀ kì yio yọ́, bi iwọ tilẹ sọ ẹ̀bun di pipọ.